News

Fiimu ọṣọ ati Awọn Ẹrọ iboju

Yoruba translation by Kiaribee Luqman Abisola

Láti bí ìdajì sẹ́ńtúúrì tó ti lalẹ̀hùn, ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìmọ̀ fíìmù àti ti móhùnmáwòrán kò í kọ ìròrí ilẹ̀ Yúróòpù sílẹ̀, nípa ìtàn rẹ̀, àbùdá ìtọpinpin àti ìlànà  ìtúpalẹ̀ rẹ̀. Bí ó  tilẹ̀ jẹ́ pé “sinímá àgbáyé” àti “sinimá olórílẹ̀-èdè-sí-orílẹ̀-èdè” ti gbìyànjú láti mú òfin àti ojúpọ̀nà rẹ̀ gbòòrò, síbẹ̀ òríṣìíríṣìí àwọn ìṣoró ńláńlá ló tún ń jẹyọ. Awọn Fíìmù àti iṣẹ́ akádá àwọn ènìyàn ilẹ̀ Afíríkà lórí fíìmù ni àwọn ènìyàn aláfun funfun àti pupa kò kà sí lọ́pọ̀ ìgbà, tàbí ká ti tilẹ̀ sọ pé wọn ti yọwọ́ rẹ̀ láwo. Èyí ń pagidínà ìpààrọ̀ aláfinúfẹ́dọ̀ṣe, èyí tó le mú wa níran ọ̀tun nípa Ẹ̀kọ́ Fíìmù àti ohun-amóhùnmáwòrán fún sẹ́ńtúrì kọkànlélógún, níbi tí àǹfààní tó lékenkà yóó ti wà fún lílo ìmọ̀-ẹ̀rọ láti fi ṣe fíìmù, kí á fi wọ́n sí orí ọ̀kẹ́ àìmọye móhùnmáwòrán, láti fi hàn pé “àgbáyé onímòóhùnmáyòrán” tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ń dàgbà kíákíá. Iṣẹ́ àkànṣe yìí ń ṣàgbéyẹ̀wò “àgbáyé onímòóhùnmáyòrán” (ó ń wo àbúdá ìrísí rẹ̀ àti àbúdà ilé-iṣẹ́ rẹ̀), ilẹ́ Áfíríkà ló gbájú mọ́ (ní pàtó, ilẹ̀ Nigeria àti ilẹ̀ Ethiopia), gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti tọ́ka agbàgbè tí a pa sinimá rẹ̀ tì jùlọ. A ó tún fẹ ẹ̀kọ́ ṣíṣe àfiwé “àgbáyé onímohùnmáwòrán” lójú- ní pàtó “àgbáyé onímohùnmáwòrán” ti Gúsù Ayé (pàtàkì jùlọ láàrin ilẹ̀ Aáfíríkà àti ilẹ̀ Éṣíà) a ó ṣàgbéyẹ̀wò ìjọra wọn, ìyàtọ̀ wọn àti ìdàgbàsókè tó jọra, tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí méjèèjí. À ń ṣe àgbéyẹ̀wò ẹ̀kọ́ fíìmù àti móhùnmáwòrán láì fi iṣẹ́ akadá nìkan ṣe,- a kò fi ti àpérò àti ìwé tí a gbé jáde nìkan ṣebí kò ṣe nípa fifi tí ọ̀nà àtinúdá àti ìjàfẹ́tọ̀ọ́-ẹni ṣe nípa lílo ọgbọ́n ìwádìí ìgbàlódé (bíi ìlànà ìtọpinpin ajẹmọ́mòóhùnmáwòrán àti fíìmù-ṣíṣe) àti nípa ṣíṣerànwọ́ láti yọwọ́ ìmúnisìn kúrò nínú Ẹ̀kọ́ Fíìmù àti ìmóhùnmáwòrán” ( a ṣe èyí nípa pípèsè àwọn ohun-èlò tí a nílò láti ṣe kòríkúlọ́ọ̀mù, sílábaọ̀sì tí ó le mú kí ẹ̀kọ́ Fíìmù jẹ́ èyí tó lábùdá káríayé). Lórí ìlànà ìtúpalẹ̀, a ó ṣe ìrànwọ́ nípa wíwo bí “àgbáyé onímòóhùnmáwòrán” (tàbí ọ̀rọ̀ mìíràn) yóó ṣe dára ju kí a lo “cinimá àgbáyé” tàbí “cinimá olórílẹ̀-èdè-sí-orílẹ̀-èdè” lọ, láti kó bí àwọn ìtàn ajẹmámóhùnmáwòrán ṣe fẹjú tó tán, kí á sì le kó ìpèsè fíìmù àti àwọn ọ̀kan-ò-jọ̀kan ọ̀nà tí a fi ń pín wọn káàkiri àgbáyé náà tán ní ìgbà ọ̀tun tí a wà yìí.

Share